Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ nipa gbólóhùn méjì kan ti ọmọniyan maa n pe ni gbogbo iṣesi láìsí inira nibẹ, ẹ̀san méjèèjì si tobi ninu òṣùwọ̀n, ati pe Oluwa wa Ajọkẹ-aye ti ọla Rẹ ga si nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì: SUBHAANALLOOHIL AZEEM, SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII; fun nǹkan ti méjèèjì ko sinu bii iroyin Ọlọhun pẹlu titobi ati pípé, ati fifọ Ọ mọ kuro nibi àléébù.