Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé adua naa ni ìjọsìn, ohun ti o jẹ dandan naa ni ki gbogbo ẹ jẹ ti Ọlọhun nìkan, yálà o jẹ adua ibeere ati wiwa nǹkan ni, bii ki o tọrọ lọ́dọ̀ Ọlọhun ohun ti o maa ṣe e ni anfaani, ati titi ohun ti o maa ko inira ba a ni ayé ati ọ̀run lọ, tabi o jẹ adua ìjọsìn, oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ti o si yọnu si ninu awọn ọ̀rọ̀ ati awọn iṣẹ ti o han ati eyi ti o pamọ, àwọn ìjọsìn ti ọkàn tabi ara tabi dúkìá. Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa mu ẹri wa lori ìyẹn, nibi ti o ti sọ pe: Ọlọhun ti ọla Rẹ ga sọ pe: {Ẹ pè Mí, kí N̄g jẹ́pè yín. Dájúdájú àwọn t’ó ń ṣègbéraga nípa jíjọ́sìn fún Mi, wọn yóò wọ inú iná Jahanamọ ní ẹni yẹpẹrẹ}