Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wẹ janaba yio bẹrẹ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, Lẹyin naa ni yio wa ṣe aluwala gẹgẹ bi o ṣe maa n ṣe aluwala fun irun, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun ori rẹ, titi ti yio fi ni lọkan pe omi ti de isalẹ irun, ti o si ti jẹ ki awọ ori mumi yo, yio waa da omi si ori ni ẹẹmẹta lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku. Aaisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ ninu igba kan náà ti a o jọ maa fi ọwọ bu omi ninu rẹ papọ.