Iya awọn olugbagbọ Maimuunah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa alaye iwẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara janaba, nigba ti o gbe omi fun un lati fi wẹ, ti o si da gaga kan bo o, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe awọn nnkan ti o n bọ yìí: Akọkọ: O da omi si ọwọ rẹ mejeeji o si fọ mejeeji ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu igba. Ikeji: O da omi pẹlu ọwọ rẹ ọtun lori osi o si fọ abẹ rẹ; lati mọ ọn kuro nibi nnkan ti o ba lẹ̀ mọ́ ọn ninu oripa janaba. Ikẹta: O fi ọwọ rẹ lu ilẹ̀, o si nù ún, lẹ́yìn náà o fọ ọ lati le mu ẹgbin kuro nibẹ. Ikẹrin: O fi omi yọ ẹnu rẹ: pẹlu ki o fi omi si ẹnu rẹ, o si mi I, o yi i lẹyin naa o tu u, o fin omi simu; pẹlu ki o fi omi simu rẹ pẹlu èémí rẹ, lẹyin naa o mu u jade lati fi mọ ọn. Ikarun-un: O fọ oju rẹ ati awọn apa rẹ mejeeji. Ikẹfa: O da omi si ori rẹ. Ikeje: O da omi si awọn toku ninu ara rẹ. Ikẹjọ: O kuro nibi aaye rẹ o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji ní ibòmíì tí kò tíì fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Lẹyin naa, o mu aṣọ kan wa fun un lati nu ara rẹ pẹlu rẹ, ṣùgbọ́n ko gba a, o bẹ̀rẹ̀ si n nu omi kuro lara rẹ pẹlu ọwọ rẹ ti o si n gbọn ọn.