explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé ìmáa ṣe imọtoto eyín pẹlu igi araak (pákò) tabi iru rẹ̀, ó máa n fọ ẹnu mọ́ tonitoni kuro nibi awọn idọti ati oorun tí kò dara ni, ati pé ó jẹ́ ọkan ninu awọn okunfa iyọnu Ọlọhun si ẹru Rẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ ìtẹ̀lé ti Ọlọ́hun àti ìdáhùn sí àṣẹ Rẹ̀, ati nítorí pé ìmọ́tótó tí Ọlọ́hun Ọba nífẹ̀ẹ́ sí wà ninu rẹ̀.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ọlá ti n bẹ fún imaa run pákò, ati pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n gba awọn ijọ rẹ̀ niyanju lati maa run pákò lọpọlọpọ ìgbà.
  • Lílo igi araak lati fi run pákò ló lọ́lá jùlọ, àmọ́ lílo búrọ́ọ̀ṣì ati ọṣẹ ifọyin máa n dipo rẹ̀ ni.