Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe awọn iwa marun-un kan n bẹ ninu ẹsin Isilaamu ati ninu sunnah awọn ojiṣẹ: Akọkọ nibẹ ni: Dida abẹ, oun ni gige awọ ti o lekun lori nnkan ọmọkunrin lori adenderi, ati gige ori awọ ti o wa lori oju ara obinrin lori aye ibi ti nnkan ọmọkunrin maa n wọle si. Ikeji nibẹ ni: Fifa irun abẹ, oun ni irun oju ara ti o wa ni àyíká oju ara. Ikẹta nibẹ ni: Gige tubọmu, oun ni gige nnkan ti o hù jade lori ete ọkunrin oke nibi ti ete ti maa hàn. Ikẹrin nibẹ ni: Gige awọn èékánná. Ikarun-un nibẹ ni: Gige irun abiya.