explain-icon

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi kiki irun pẹlu ikalẹ ounjẹ ti ẹmi olukirun n fa síbẹ̀, ti ọkan rẹ si n so mọ ọn. Gẹgẹ bẹẹ ni o ṣe kọ kuro nibi kiki irun pẹlu dídá Al-Akhbathaan- awọn mejeeji ni itọ ati igbẹ- padà, nitori kiko airoju rẹ pẹlu dídá ẹgbin náà padà.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • O tọ fun olukirun lati gbé gbogbo nnkan ti o le maa ko airoju ba a nibi irun rẹ jìnnà ṣíwájú ki o to wọnu rẹ.