explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣọ wa lara kuro nibi lílọ bá adagbigba- orúkọ kan ni ti o kárí fun yẹmiwo, ati awòràwọ̀, ati ẹni ti n tẹ yanrìn, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ninu awọn ti maa n mu ẹri wa fun mímọ kọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn itisiwaju kan ti o maa n lò- ati pe ọ̀wọ́ọ pe èèyàn kan bi i leere nipa nǹkan kan ninu kọ̀kọ̀, Ọlọhun ko nii fun un ni ẹsan ìrun rẹ fun ogójì ọjọ́; ki ìyẹn le maa jẹ ìyà fun un lórí ẹṣẹ ńlá yìí.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣíṣe iṣẹ yẹmiwo ni eewọ, ati lílọ ba àwọn yẹmiwo, ati bibi wọn nipa kọ̀kọ̀.
  • Èèyàn lè má gba ẹ̀san itẹle àṣẹ Ọlọhun ki o le jẹ ìjìyà fun un lórí ẹṣẹ.
  • O maa ko sinu hadiisi naa nǹkan ti a n pe ni ìràwọ̀ ati wiwo o, ati kíkà àtẹ́lẹwọ́ àti ife-ìmumi- kódà ki èèyàn kan fẹ mọ̀ nipa rẹ lásán-; torí pé gbogbo ìyẹn wa ninu iṣẹ yẹmiwo ati pípe apemọra ìní-ìmọ̀ kọ̀kọ̀.
  • Ti eyi ba jẹ ẹsan ẹni tí ó lọ ba yẹmiwo, bawo wa ni ẹsan yẹmiwo gan fúnra rẹ ṣe maa ri?
  • Ìrun ogójì ọjọ́ yẹn maa tó o, kii ṣe dandan fun un ki o da a pada, ṣùgbọ́n ko nii gba ẹsan rẹ.