explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo pé ẹnikẹni tí ó bá fi nkan miran búra yatọ si Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, onitọhun ti ṣaigbagbọ si Ọlọhun, tabi ka ní ó ti ṣẹbọ pẹlu Rẹ̀; nítorí pé ìbúra ní í ṣe pẹ̀lú ìgbétítóbi fún nkan tí a fi búra, títóbi sì jẹ́ ti Ọlọ́hun Allah nìkan ṣoṣo; nitori naa, a kò gbọdọ̀ bura pẹlu nkankan ayafi Ọlọhun Allah ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀, Mimọ ni fun Un, Ati pé ìbúra yii wà ninu ẹbọ kekere; ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó búra bá fi gbé títóbi fun nkan tó fi bura gẹgẹ bii ìgbétítóbi fún Ọlọ́hun Allah tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ; nigba naa, ó ti wà ninu ẹbọ nla niyẹn.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Dajudaju fífi ibura gbé titobi fún nkan jẹ́ ẹ̀tọ́ fún Ọlọhun Allah, mimọ ni fun Un, nitori naa a kò gbọdọ búra pẹlu nkankan ayafi Ọlọhun ati awọn orukọ Rẹ̀ ati awọn iroyin Rẹ̀.
  • Ìtaraṣàṣà awọn Sahabe lori pipaṣẹ rere ati kikọ aburu, paapaa julọ tí aburu naa ba nii ṣe pẹlu ẹbọ tabi aigbagbọ.