Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ko si ẹru kan ti yio da ẹṣẹ kan, ti yio wa se aluwala daadaa, lẹyin naa ti yio ki irun rakaah meji pẹlu aniyan ituuba kuro nibi ẹṣẹ rẹ yii, lẹyin naa ti o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun fi ori jin in. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ka ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe: ﴾Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni).﴿ [Āl ‘Imraan: 135].