explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ri arakunrin kan ti o n jẹun pẹlu ọwọ rẹ osi, o wa pa a láṣẹ lati jẹun pẹlu ọwọ rẹ ọtun, Arakunrin naa wa da a lohun ni ti igberaga ati irọ pe oun ko ni ikapa! Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹbi le e pe ki wọn ṣe jijẹ pẹlu ọwọ ọtun leewọ fun un, Ọlọhun ba gba adura Anabi Rẹ pe ki ọwọ ọtun rẹ rọ, ko si lee gbe e si ẹnu rẹ lẹyin ìyẹn pẹlu oúnjẹ tabi nǹkan mimu.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Jijẹ dandan jijẹun pẹlu ọwọ ọtun, ati jijẹ eewọ jijẹun pẹlu ọwọ osi.
  • Ṣíṣe igberaga nibi titẹle awọn ofin Sharia maa n mu ẹni ti o ba ṣe lẹtọọ si iya.
  • Apọnle Ọlọhun fun Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu gbigba adura rẹ.
  • Ṣíṣe pipaṣẹ pẹlu daadaa lofin ati kikọ kuro nibi ibajẹ ni gbogbo isẹsi koda nibi isẹsi jijẹ.