Umar ọmọ Abu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -, ọmọ iyawo anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n ṣe ummu salamah - ki Ọlọhun yọnu si i - o si wa ni abẹ itọju rẹ ati amojuto rẹ -, n sọ pé òun jẹ ẹni ti o maa n gbe ọwọ rẹ kaakiri ẹgbẹẹgbẹ abọ ni asiko ounjẹ, nitori naa Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa kọ ọ ni awọn ẹkọ mẹta ninu awọn ẹkọ jijẹ: Alakọkọọ rẹ ni: Gbólóhùn "BismilLah" ni ibẹrẹ ounjẹ. Ati pe ẹlẹẹkeji ni: jíjẹ ounjẹ pẹlu ọwọ ọtun. Ati pe ẹlẹẹkẹta rẹ ni: Jijẹ nibi ẹgbẹ ti o ba sunmọ ọn ninu oúnjẹ.