explain-icon

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ; ìyẹn ni pe ẹni ti n kirun maa fi ibi ti o ga ju ti o si niyi ju ninu ara rẹ lé ilẹ̀ ni ti ìtẹríba ati irẹlẹ fun Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ti o si wa ni iforikanlẹ. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wa pàṣẹ ṣíṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ, o maa wa kójọ ninu ìyẹn irẹlẹ fun Ọlọhun pẹlu ọ̀rọ̀ ati ìṣe.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Itẹle àṣẹ Ọlọhun maa n le ẹrú kún ni isunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  • A fẹ́ ki a maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ; torí pé ó wa ninu awọn ààyè gbigba adua.
explain-icon

Àlékún