explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé: Dajudaju Ọlọhun maa n nífẹ̀ẹ́ sí mímú awọn ofin idẹkun Rẹ ti O ṣe wọn lofin wa, ninu awọn nnkan ti O ṣe wọn ni fifuyẹ nibi awọn idajọ ati ijọsin, ati ṣíṣe irọrun nibẹ fun awọn ẹni ti a la iwọ Ọlọhun bọ lọrun fun idi kan- gẹgẹ bii dindin irun ku ati dida a pọ ni ori irin ajo-, Gẹgẹ bi O ṣe nífẹ̀ẹ́ si mimu awọn ofin ti wọn jẹ dandan wa, ninu awọn alamọri ti wọn jẹ dandan; nitori pe aṣẹ Ọlọhun nibi awọn ìdẹkùn ati awọn nnkan ti wọn jẹ dandan jẹ ọ̀kan.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- lori awọn ẹru Rẹ, ati pe Ọlọhun- mimọ ni fun Un- nífẹ̀ẹ́ si mimu nnkan ti o ba ṣe lofin wa ninu awọn idẹkun.
  • Pipe ofin sharia yii, ati gbigbe ìdààmú rẹ kuro fun Musulumi.