Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé òfin kan ti o kárí nibi awọn nǹkan, o si pin si mẹta ninu ṣẹria: Ẹ̀tọ́ ti o fi ojú hàn, ati eewọ ti o fi ojú hàn, ati awọn alamọri kan ti wọn ruju ti idajọ wọn kò hàn nipa pe ṣe ẹtọ ni abi eewọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu awọn èèyàn ko mọ idajọ wọn. Ẹni ti o ba gbe àwọn nǹkan iruju yẹn jù silẹ, ẹsin rẹ maa ni àlàáfíà pẹ̀lú jíjìnnà sí kiko sinu nǹkan eewọ, ọmọlúwàbí rẹ naa si maa ni àlàáfíà kuro nibi ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn pẹ̀lú nǹkan ti wọn yoo fi maa bu u ti o ba ṣe nǹkan ìríjú yii. Ẹni ti ko ba jìnnà si awọn nǹkan ìríjú, ninu ki o ko sinu nǹkan eewọ, tabi ki àwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ọmọlúwàbí rẹ. Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi àkàwé kan lélẹ̀ lati ṣàlàyé iṣesi ẹni tí o ba n ṣe àwọn nǹkan iruju pe o da gẹgẹ bii adaranjẹ ti n da ẹran rẹ jẹ ni tòsí ilẹ̀ kan ti ẹni tí ó ni i ti da aabo bo o, o sunmọ ki awọn ẹran rẹ jẹ ninu ilẹ̀ ti a da aabo bo yii torí wiwa wọn ni tòsí ibẹ, bẹ́ẹ̀ naa ni ẹni ti n ṣe nnkan ti ìríjú wa ninu ẹ, pẹ̀lú ìyẹn o ti n sunmọ nǹkan eewọ, o si sunmọ ki o ko sinu rẹ. Lẹyin rẹ ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé baaṣi ẹran kan n bẹ ninu ara (oun naa ni ọkàn), ara yoo maa dáa pẹ̀lú dídára rẹ, o si maa bajẹ pẹ̀lú bibajẹ rẹ.