explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ti ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti inawo wọn jẹ dandan fun un, gẹgẹ bii iyawo rẹ ati awọn obi rẹ mejeeji ati ọmọ rẹ ati awọn ti wọn yatọ si wọn, ti o n fi ìyẹn sunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ti o n reti ẹsan nnkan ti o n na lọdọ Rẹ, dajudaju ẹsan saara n bẹ fun un.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Gbígba ẹsan ati laada pẹlu ninawo lori awọn ara ile.
  • Mu’mini maa n wa ojú rere Ọlọhun ati ẹ̀san ti n bẹ lọdọ Rẹ nibi iṣẹ rẹ.
  • O lẹtọọ lati ni aniyan daadaa nibi gbogbo iṣẹ, ninu ìyẹn ni iṣesi ninawo lori awọn ara ile.