explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- tọrọ iyẹpẹrẹ ati idojuti titi o fi da gẹgẹ bii pe o ki imu rẹ bọ inu erupẹ- o paara rẹ lẹẹmẹta- wọn wa bi i leere pé: Tani ẹni yii irẹ ojiṣẹ Ọlọhun ti o ṣepe fún? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ẹni ti o ba awọn obi rẹ mejeeji nigba ogbo- ọkan ninu awọn mejeeji tabi awọn mejeeji-, ti wọn ko wa jẹ okunfa wiwọ alujanna rẹ; ìyẹn maa ri bẹẹ torí aiṣe daadaa si awọn mejeeji ati ṣiṣẹ awọn mejeeji.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ijẹ dandan ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji ati pe o wa ninu awọn okunfa wiwọnu alujanna, pataki julọ nígbà ogbo wọn ati lilẹ wọn.
  • Ṣiṣẹ awọn obi mejeeji wa ninu awọn ẹṣẹ ńlá.
explain-icon

Àlékún