Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju olukirun ti o ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ ti ko mọ iye ti o ki, boya mẹta ni tabi mẹrin? Ki o gbe onka ti o lekun ti o n ṣe iyemeji nipa rẹ jinna ki o ma lo o: mẹta ni o da a loju, o maa ki rakah kẹrin, lẹyin naa o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ. Ti o ba ṣe pe nnkan ti o ki jẹ mẹrin ni òtítọ́; o maa di marun-un pẹlu alekun rakah kan, ti iforikanlẹ mejeeji ti igbagbe maa jẹ ijirọ fun rakah kan, onka naa maa jẹ nǹkan ti eéjì le pin ko nii jẹ nǹkan tí eeji ko le pin: Ti o ba wa ki mẹrin pẹlu rakah ti o lekun; o maa jẹ pe o ti ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun un laisi alekun tabi adinku. Iforikanlẹ igbagbe mejeeji jẹ iyẹpẹrẹ fún shaytaan ati ile e jina, ati lile e jina si erongba rẹ; torí pé o ti da irun rẹ ru mọ ọn l'oju, ti o si tun fẹ ba a jẹ, ati pe irun ọmọ Anabi Ādam pe nígbà tí o ba ti tẹle aṣẹ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pẹlu iforikanlẹ eleyii ti èṣù yapa nitori rẹ, nígbà tí o kọ lati tẹle àṣẹ Ọlọhun pẹlu fifi orikanlẹ fun Ādam.