Ẹnikan ninu awọn saabe lobinrin fi ẹjọ àìdá ẹjẹ rẹ sun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa pa a láṣẹ kí ó má kirun ni odiwọn igba ti ẹjẹ nnkan oṣu rẹ fi maa n dè é mọle ṣíwájú ki àlámọ̀rí pajawiri yii o to ṣẹlẹ̀ si i, lẹyin naa o maa wẹ, o si maa kirun, o si jẹ ẹni ti maa n fínnú-fíndọ̀ wẹ fun gbogbo irun kọọkan.