Faatimah ọmọ Hubaysh beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni o wa sọ pe: Dajudaju ẹjẹ o ki n da lara mi ati pe o si maa n wa titi di igba ti kii ṣe igba ẹjẹ nkan oṣu, njẹ idajọ iyẹn le jẹ idajọ ẹjẹ nkan oṣu bii ti maa wa maa gbe irun ju silẹ? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun un pe: Dajudaju ẹjẹ awaada ni, oun si ni ẹjẹ aisan kan ti o maa n ṣẹlẹ lati ipasẹ jija iṣan kan nibi apo ibimọ, ati pe kii ṣe ẹjẹ nkan oṣu, Ti asiko ẹjẹ nkan oṣu ba de, eyi ti o maa n ri ẹjẹ nkan oṣu níbẹ̀ lori ìṣesí oṣooṣu rẹ siwaju ki o to lugbadi aisan ẹjẹ awaada, ki o yaa fi irun ati aawẹ ati nkan ti o yatọ si mejeeji silẹ ni awọn nkan ti wọn kọ fun ẹni ti n ri ẹjẹ nkan oṣu kuro nibẹ ni asiko ẹjẹ nkan oṣu. Ti odiwọn igba yẹn ba ti wa tan, nigba naa wa jẹ ẹni ti o ti mọra kuro nibi ẹjẹ nkan oṣu, ki o yaa fọ aaye ẹjẹ yẹn, lẹyin naa ki o wẹ ara rẹ ni iwẹ ti o pe lati gbe ẹgbin kuro, lẹyin naa ki o wa ki irun.