Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Jibril ko yẹ ni ẹni tí n pààrà fun un ti o si n pa a láṣẹ láti ni akolekan aládùúgbò ti ilé rẹ sunmọ, Mùsùlùmí ni tabi Kèfèrí, mọlẹbi ni tabi ẹni tí kii ṣe mọ̀lẹ́bí, pẹlu ṣiṣọ iwọ̀ rẹ, ki eeyan ma si fi suta kan an, ki èèyàn si maa ṣe daadaa si i, ki èèyàn si maa ṣe suuru lori suta rẹ, titi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi lérò pe imisi maa sọ̀kalẹ̀ pé ki a maa fun un ninu dúkìá aládùúgbò rẹ ti o ba fi silẹ lẹ́yìn iku rẹ latara bi o ṣe bàbàrà iwọ̀ rẹ, ati bi Jibril ṣe n pààrà rẹ.