Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan». O ni alaafia - Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa
explain-icon

Àlàyé

Saabe abiyi tii ṣe Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - n funni niroo pe: Awọn jade ni alẹ kan ti ojo pọ gan ti okunkun naa si dudu kirikiri, lati lọ wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-; ki o le ki irun fun wọn, ti wọn si ri i, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: "Qul" iyẹn ni pe: ka, ko si ka nkankan, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tun ọrọ rẹ wi fun un, ni Abdullāh wa sọ pe: Kini ki n ka irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Ka suuratul Ikhlaas {Qul Uwal Laahu ahad}, ati Al-Mu‘awwidhatayn {Qul a‘uudhu bi robbil falaq}, ati {Qul a‘uudhu bi robbin naas}, ni asiko irọlẹ, ati asiko aarọ, ni ẹẹmẹta yio maa sọ ọ kuro nibi gbogbo aburu, ti yio si la ọ kuro nibi gbogbo ibajẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣiṣe ni sunnah kika suuratul Ikhlaas ati qul a‘uudhu mejeeji (Falaqi ati Naasi) ni aarọ ati irọlẹ ati pe isọ ni wọn jẹ kuro nibi gbogbo aburu.
  • Ọla ti n bẹ fun kika suuratul Ikhlaas ati Qul a‘uudhu mejeeji.