Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe eemọ nipa ọrọ mumini ati awọn iṣesi rẹ ni ti daadaa; ìyẹn ni pe gbogbo ìṣesí rẹ patapata ni oore, ti ìyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini; Ti daadaa ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ fun Ọlọhun lori rẹ; ti yio si gba ẹsan pẹlu ọpẹ dida, Ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru ti yio si tun retí ẹsan lọdọ Ọlọhun, ti yio si tun gba ẹsan suuru, nitori naa inu ẹsan ni o wa ni gbogbo ìṣesí rẹ.