explain-icon

Àlàyé

Umar - ki Ọlọhun yọnu si i - funni niroo pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ri arakunrin kan ti o ti pari aluwala rẹ, ti o wa fi deedee eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ ti ko mu omi aluwala de ibẹ, Ni o wa sọ lẹni ti o na'ka si aaye aṣeeto yẹn: Pada ki o lọ ṣe aluwala rẹ daadaa ki o si pe e ki o si tun fun oríkèé kọọkan ni ẹtọ rẹ ninu omi, Ni arakunrin naa ba pada ti o sì lọ pe aluwala rẹ lẹyin naa ni o kirun.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Jijẹ dandan yiyara lati pàṣẹ daadaa, ati titọ alaimọkan ati onigbagbe sọnà, pataki julọ ti bibajẹ ijọsin ba maa jẹ yọ latara aidara yẹn.
  • Jijẹ dandan fifi omi kari gbogbo ara, ati pe ẹni ti o ba fi ipin (aaye) kan ninu oríkèé ara silẹ - koda ki o ma to nkankan - aluwala rẹ o ni alaafia o si tun jẹ dandan fun un ki o tun un ṣe tí alaafo yẹn ba ti gun.
  • Ṣiṣe imaa ṣe aluwala daadaa ni ofin, ati pe iyẹn ni pipe e ati ṣiṣe e daadaa lori ojupọna ti ofin fi pàṣẹ rẹ.
  • Ẹsẹ mejeeji ninu awọn oríkèé aluwala ni wọ́n wa, pipa mejeeji o si lẹẹ tọ, bí kò ṣe pe ko si ibuyẹ kuro nibi fifọ (ẹsẹ mejeeji).
  • Yiyara ṣe awọn oríkèé aluwala tẹle ara wọn jẹ nkan to lẹẹ tọ, ni èyí ti o ṣe pe yio fọ oríkèé kọọkan ṣíwájú ki èyí tí o ṣaaju rẹ o to gbẹ.
  • Aimọkan ati igbagbe wọn o lee bi ọranyan wo, nkan ti wọn le mu kuro ni ẹṣẹ, nitori naa arakunrin ti ko ṣe aluwala rẹ daadaa latara aimọkan rẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o bi ọranyan wo fun un, oun naa ni aluwala, o tun pa a l'aṣẹ ki o tun un ṣe ni.
explain-icon

Àlékún