explain-icon

Àlàyé

Ti mẹwa igbẹyin ninu osu Ramadan ba tide Anọbi (Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba) aa maa gbiyanju ninu rẹ pẹlu ìjọsìn ati itẹle aṣẹ Ọlọhun, aa si maa se ọpọlọpọ awọn oriṣirisi iṣẹ o loore ati awọn oníranran iṣẹ daada ati ìjọsìn fún Ọlọhun eyi ti o pọ ju bi se ma ngbiyanju ni awọn ọjọ míràn lọ, ori bẹẹ nitori titobi ati ọlá ti nbẹ fún awọn òru náà ati nítorí wiwa òru abiyi.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Iseni lójúkòkòrò lati se ọpọlọpọ iṣẹẹre ati awọn ọna itẹle aṣẹ Ọlọhun ninu osu Ramadan lapapọ ati ni mẹwa igbẹyin ninu rẹ ni adayanri.
  • Mẹwa igbẹyin ninu osu Ramadan aa maa bẹrẹ lati òru ọkanlelogun titi di ipari oṣù.
  • ifẹ ki a lo anfaani awọn asiko ti o lọ́lá fún itẹle aṣẹ Ọlọhun.