Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala pẹlu ṣíṣe àkíyèsí awọn sunna aluwala ati awọn ẹkọ rẹ, iyẹn maa wa ninu awọn okunfa pipa awọn ẹṣẹ rẹ ati pipa àṣìṣe rẹ, titi awọn ẹṣẹ rẹ yoo fi jade labẹ awọn èékánná ọwọ rẹ mejeeji ati ti ẹsẹ rẹ méjèèjì.