explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun ọranyan koda ki aluwala rẹ o ma bajẹ; iyẹn ni lati fi gba ẹsan ati ọla. O si tun lẹtọọ ki o ki ju irun ọranyan ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan lopin igba ti o ba ṣi ni aluwala.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Eyi ti o pọju ninu iṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – oun ni ṣiṣe aluwala fun gbogbo irun; lati fi wa eyi ti o pe julọ.
  • Nǹkan ti a fẹ ni ṣíṣe aluwala fun gbogbo irun.
  • Lilẹtọọ kiki irun ti o pọ ju ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan.