Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni tí o ba gba aawẹ oṣù Ramadan ni ti igbagbọ ninu Ọlọhun, ati gbigba ìjẹ-ọran-anyan aawẹ ni ododo, ati ohun ti Ọlọhun pèsè kalẹ fun awọn alaawẹ bii ẹsan ti o pọ̀, ni ẹni tí n gbèrò ojú-rere Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ti kọjá jin in.