Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pé ala daada ti o dun ni ninu láti ojú orun lati ọdọ Ọlọhun ni ti nwa, bẹẹ ni alakala ti ko da ti o si nbani nínú jẹ, lati ọdọ èṣù ni ti nwa. Ẹni k'ẹni ti o bá lala ri nkan ti kò wu u, ki o ya tutọ sí apá òsì rẹ, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburu ala naa, ala náà ko nii ko aburú ba nitoripe Ọlọhun ti fi gbolohun ti o sọ yẹn se okunfa àkóyọ nibi nkan ti kò fẹ ti o le t'ara ala tí o la ṣẹlẹ.