Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa bá a - fún wa ní ìró pé dajudaju àlá daada tí ó ń múnú ẹni dùn lójú orun wá lati ọdọ Ọlọhun, Anọbi sì tọ wa sọna pe kí a fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ẹni naa sì lè sọ jade, ṣugbọn ti ó bá lálàá rí nkan tí kò fẹ́, tabi nkan tó ba a nínú jẹ́, lati ọdọ eṣu ni ó tiwa, ki o yáa wá iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, kí ó má ṣe rọ́ àlá náà tabi sọfún ẹnikankan, dájúdájú kò nii kó ìnira bá a nígbàtí o jẹ wipe Ọlọhun ti fi nkan táa sọ yii ṣe okunfa ọlà ati akoyọ kuro nibi nkan ti a kò fẹ, eyi ti ó lè fẹ ṣẹlẹ latara àlá náà.