Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, gba wa niyanju lati gbẹkẹle Ọlọhun lati mu anfaani wa ati lati yago fun ipalara ninu ọ̀rọ̀ aye ati ẹsin. Ko si ẹni ti o le fun èèyàn ni nǹkan tabi fi nǹkan dun èèyàn, tabi ko inira ba èèyàn tabi ṣe èèyàn ni anfaani ayafi Ọlọhun Ọ̀gá-ògo, Ki a si ṣe awọn okunfa ti o maa mu anfaani wa, ti o si maa dènà ipalara, pẹlu gbigbẹkẹle Ọlọhun ti òdodo, ti a ba ṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọhun maa pese fun wa bi O ti n pese fun awọn ẹyẹ ti wọn n jade ni owurọ pẹ̀lú ebi. Lẹ́yìn naa wọn maa pada ni irọlẹ ti ikun wọn si ti kún, ati pe iṣe ti ẹyẹ yii jẹ ọkan ninu awọn ọ̀nà igbiyanju lati wa jíjẹ-mímu, laisi igbẹkẹle asán ati ìmẹ́lẹ́.