Annabi -kí ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ o maa ba- n paṣẹ fún àwọn tí ń ṣàkóso ogún pínpín pé kí wọ́n pín (ogun ti oku fi silẹ) fún àwọn tí ó tọ si, ni ìpín ti o ṣe dede ofin (shari'a), gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́hun ṣe fẹ́. Nítorí náà, a máa fún àwọn onípin tí a ti sọ ìpín wọn di mímọ́ nínu tira Ọlọ́hun ní ipin wọn, tí awọn ìpín naa si jẹ: ìdáméjì ninu ida mẹta ogún, idankan idamẹta, idafa, ìdajì, idamẹrin, ati idamejọ ogún, ohun tí o ba wa sẹku lẹyin naa, a o fún ẹni tí ó sunmọ́ oku jù lọ ninu awọn ọkùnrin, ti wọ́n sì ń pè wọn ní Al-‘asabah (àwọn ìbátan ọkùnrin tí ń jogún ohun tí ó sẹkù lẹyin ti a pin ogun tan).