Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju iwẹ ọjọ Jimoh kanpa o da gẹgẹ bii ọranyan fun gbogbo ọkunrin ti o ti balaga ninu awọn musulumi ninu awọn ti Jimoh jẹ dandan fun. Ati pe ki o mọ awọn eyin rẹ pẹlu pákò ati nkan ti o jọ ọ. Ati ki o lo lọ́fíńdà pẹlu èyíkéyìí oorun aladidun.