Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé adehun iya ti o le koko to wa lori pe dajudaju ẹni ti o ba pa ẹni ti a gba adehun lọwọ rẹ- oun ni ẹni ti o wọ ilẹ̀ Isilaamu ninu awọn alaigbagbọ pẹlu adehun ati ifọkanbalẹ- pe ẹni naa ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ maa jẹ ijiina irin ogoji ọdun.