explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn adari kan maa jẹ lori awọn Musulumi ti wọn ma maa wuwa imọtaraẹninikan pẹlu awọn dukia Musulumi ati eyi ti o yàtọ̀ si i ninu awọn àlámọ̀rí aye, ti wọn ma maa na an gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ, ti wọn ma maa kọ fun awọn Musulumi nibi ẹtọ wọn nibẹ. O si maa waye lati ọwọ wọn, awọn àlámọ̀rí kan ti wọn kọ ninu ẹsin. Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- beere pé: Ki ni awọn maa ṣe nibi isẹsi yẹn? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn pe didana owo wọn ko lee kọ fun yin lati jẹ ki ẹ kọ nnkan ti o jẹ dandan fun yin si wọn ninu gbigbọ ati itẹle, bi ko ṣe pe ki ẹ ṣe suuru ki ẹ si gbọ́ ki ẹ si tẹle,ẹ ko si gbọdọ fa àlámọ̀rí mọ wọn lọwọ, ki ẹ si beere ẹtọ ti o jẹ ti yin lọdọ Ọlọhun, ati pe ki O tun wọn ṣe, ki O si ti aburu wọn ati abosi wọn lọ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Hadiisi naa wa ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti o sọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu ìjọ rẹ ti o si ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi o ṣe sọ.
  • Ṣíṣe lẹtọọ sisọ fun ẹni ti adanwo fẹ kan nípa nnkan ti wọn maa mu ṣẹlẹ̀ si i ninu àdánwò; lati pese ara rẹ kalẹ, ti o ba ti wa de ba a yoo jẹ onisuuru ti o maa reti ẹsan lati ọdọ Ọlọhun.
  • Idirọmọ Kuraani ati sunnah maa n mu ni jade kuro nibi awọn fitina ati iyapa.
  • Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbọ ati itẹle fun awọn adari pẹlu daadaa, ati aima jade le wọn lori, ko da ki abosi ṣẹlẹ̀ lati ọdọ wọn.
  • Lilo ọgbọ́n ati itẹle sunnah ni asiko awọn fitina.
  • O jẹ dandan fun ọmọniyan lati ṣe ẹtọ ti o jẹ dandan fun un, ko da ki nnkan kan ṣẹlẹ̀ si i ninu abosi.
  • Ẹri n bẹ nibẹ lori ipilẹ: Ṣíṣe ẹsa eyi ti o rọrun julọ ninu aburu meji tabi eyi ti o fuyẹ julọ ninu inira meji.