explain-icon

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹ èpè lé gbogbo ẹni tí ó bá jẹ alaṣẹ lori àlámọ̀rí kan fun awọn Mùsùlùmí, bóyá o kéré ni tabi o tóbi, bóyá ti gbogbogboo ni tabi fun apá ibikan sọ́, tí o wa fi ara ni wọn ti ko ṣàánú wọn, pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa san an lẹsan latara irú iṣẹ rẹ pẹlu pe ki o fi ara ni oun náà. Ẹni tí ó bá wa ṣàánú wọn ti o si ṣe àlámọ̀rí wọn ni irọrun, pe ki Ọlọhun ṣàánú tiẹ̀ naa ki O si ṣe àlámọ̀rí rẹ ni irọrun.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • O di dandan fún ẹni tí o ba jẹ alaṣẹ lori nnkan kan ninu àlámọ̀rí àwọn Musulumi ki o ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn bi o ba ṣe kápá mọ.
  • Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ.
  • Òṣùwọ̀n ohun ti a maa kà kún ninu ìwà pẹ̀lẹ́ tabi ilekoko ni ohun ti ko ba ti tako Kuraani ati Sunna.
explain-icon

Àlékún