explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju irun o le ni alaafia ayaafi pẹlu kika suuratul Faatiha, o si jẹ origun kan ninu awọn origun irun nibi gbogbo rakaha.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Nkankan o le dipo kika Faatiha yatọ si i pẹlu nini ikapa lati ka a.
  • Bibajẹ rakaha eleyii ti wọn o ka Faatiha ninu rẹ, lati ọdọ ẹni ti o finu-findọ ṣe e, ati alaimọkan ati onigbagbe; nitori pe dajudaju origun ni i, ati pe awọn origun o lee bọ lailai.
  • Kika Faatiha o maa bọ fun ero ẹyin nigba ti o ba ba imaamu ni rukuu.