Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere nipa ìyapa erongba awọn jagunjagun: Ẹni ti n jagun ni ti ijẹ akin, ati ẹni ti n jagun ni ti igbonara ati ẹni ti n jagun lati mọ ipo rẹ l'ọdọ awọn eeyan, ewo ni o wa ni oju-ọna Ọlọhun ninu wọn? Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe dajudaju ẹni ti n jagun si oju-ọna Ọlọhun ni: Ẹni ti n jagun lati jẹ ki o jẹ pe ọrọ Ọlọhun ni yio leke.