explain-icon

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n kilọ fun ẹni ti o ba da oju ija kọ awọn Musulumi pẹlu nnkan ìjà, lati le dẹru ba wọn ati lati fi tipa gba nkan wọn, nitori naa ẹni ti o ba ṣe ìyẹn lai lẹtọọ, o ti da ọran nla ati ẹṣẹ nla kan ninu awọn iya ẹṣẹ, ti o si lẹtọọ si adehun iya ti o le.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ikilọ ti o le kuro nibi ki Musulumi o ba awọn ọmọ-iya rẹ Musulumi ja.
  • Ninu awọn ibajẹ ti o tobi julọ ni orilẹ ni yiyọ nkan ija si awọn Musulumi, ati ṣiṣe ibajẹ pẹlu ipaniyan.
  • Adehun iya ti wọn sọ yẹn ko ko ìjà pẹlu ẹtọ sinu, gẹgẹ bii biba awọn olutayọ ala ati awọn aṣebajẹ ati awọn ti o yatọ si wọn ja.
  • Ṣiṣe idẹruba awọn Musulumi pẹlu nkan ija tabi eyi ti o yatọ si i ni eewọ– koda ki o jẹ ni ọna awada -.
explain-icon

Àlékún