Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o fi eniyan mọna ti o si tọka ti o si ṣe awọn eniyan lojukokoro lọ sibi oju ọna kan ti ododo ati daadaa n bẹ nibẹ pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹsan ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu ẹsan olutẹle náà. Ati pe ẹni ti o ba dari ti o si tọka awọn eniyan lọ sibi oju ọna ibajẹ ati aburu, ti ẹṣẹ ati àṣìṣe tabi ti àlámọ̀rí ti ko lẹtọọ n bẹ nibẹ, pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹṣẹ ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn.