Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n fun wa ni iro nipa nnkan ti isesi awọn kan ninu ìjọ rẹ maa wa lori rẹ lẹyin ti o ba lọ tan, oun ni itẹle oju ọna Juu ati Nasara nibi awọn adisọkan wọn ati awọn iṣe wọn ati awọn àṣà wọn ni itẹle kan ti o péye ti o lágbára ni odiwọn ibu atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa, koda ki wọn wọnu isa agilinti awọn wọnyii maa wọle lẹyin wọn.