'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa apakan ninu awọn iṣesi rẹ ti o jẹ ẹsa pẹlu rẹ (Anabi) - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu rẹ ni pe: O maa n wẹ latara janaba pẹlu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa, ti awọn mejeeji si maa n bu omi ninu rẹ papọ. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sunmọ ọn ti o si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu, ó maa pa a láṣẹ lati bo ara rẹ lati idodo de orunkun, ti o si maa fi ara rò ó laisi ibalopọ. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ṣe itikaaf ninu mọsalasi, yoo si gbe ori rẹ jade si 'Aaisha yio si wẹ ẹ ti o si wa ninu ile rẹ ni ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu.