Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni kọọkan ti Ọlọhun ba fi ṣe olori fun awọn èèyàn, boya o jẹ àṣẹ ti gbogbogboo ni gẹgẹ bii alaṣẹ ìlú, tàbí àṣẹ ti kii ṣe ti gbogbogboo, gẹgẹ bii ọkùnrin ninu ile rẹ, ati obinrin ninu ile rẹ, ti o wa ṣe ohun ti o kù díẹ̀ káàtó nibi ẹ̀tọ́ àwọn ti n bẹ ni abẹ rẹ, o tun rẹ́ wọn jẹ, ko si gba wọn ni imọran, o wa fi iwọ̀ wọn ti ẹsin ati ayé ráre, o ti ni ẹ̀tọ́ si ìjìyà ti o le koko yìí.