Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ máa bà) pa wà lasẹ lati gbógun ti alaigbagbọ, ki a sì ná ìgbìyànjú láti dájú kọ won pẹlu gbogbo ọnà tí a ni ìkápá le lórí nítorí kì gbólóhùn ati ọrọ Ọlọhun le wa loke, nínú ìgbìyànjú náà ni: Alakọkọ: nina owó àti dukia lati fi gbógun ti won, bí rírà nkan ijagun, ati ìnáwó lórí awon jagunjagun ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ẹlẹkeji: ki a jàdé pẹlu emi ati ará lati lọ pàdé won ati lati da won pàdà. Ẹlèkẹta: pẹlu pípé won síbi ẹṣin Islam yi pẹlú ahán, ati ifi idi ọrọ ati ẹri rinlẹ fún won ati ijagbe mọ won ati ìfun won lèsi.