explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye adehun iya ti o le gidi fun ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu rẹ, pẹlu pe ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan rẹ di aworan Kẹtẹkẹtẹ.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • O n bẹ fun ero ẹyin pẹlu imaamu rẹ ìṣesí mẹẹrin: Wọn kọ kuro nibi mẹta, oun naa ni: Gbigba iwaju ati biba dọgba ati pipẹ lẹyin, ati pe eyi ti wọn ṣe lofin fun ero ẹyin ni: Titẹle imaamu.
  • Jijẹ dandan itẹle ero ẹyin fun imaamu rẹ ninu irun.
  • Adehun iya pẹlu yiyi aworan ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju Imaamu sí aworan Kẹtẹkẹtẹ nkan ti o rọrun ni, oun si wa ninu pipa aworan da.