Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ni ọkan ninu awọn irin-ajo rẹ, ni o wa ṣe aluwala, Nigba ti o wa débi fifọ ẹsẹ mejeeji, Al- Mughiirah ọmọ Shu‘bah - ki Ọlọhun yọnu si i - na ọwọ rẹ mejeeji lati bọ nkan ti o wa ni ẹsẹ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni abọsẹsẹ alawọ lati fọ ẹsẹ rẹ mejeeji. Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Fi mejeji silẹ ma bọ wọn, torí pé dajudaju mo ti ẹsẹ mi mejeeji bọ inu abọsẹsẹ alawọ mejeeji ti mo si wa lori imọra, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa fi ọwọ pa abọsẹsẹ alawọ rẹ mejeeji lati fi jirọ fifọ ẹsẹ mejeeji.