Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ninu awọn majẹmu nini alafia irun ni: Imọra, nitori naa o jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ ki irun ki o ṣe aluwala ti o ba ṣe pe ọkan ninu awọn nkan ti o maa n ba aluwala jẹ ba ṣẹlẹ si i; gẹgẹ bii igbẹ tabi itọ tabi oorun tabi nkan ti o yatọ si i.