Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba

Lati ọdọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba.
O ni alaafia - Al-Bukhari as Mu‘allaq/hanging, with a decisive form

‘Āisha iya gbogbo mu’mini – ki Ọlọhun yọnu si i – n sọ pe dajudaju Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti ojukokoro rẹ pọ gidi gan lori riranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati pe dajudaju o jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba ati aaye ati ìṣesí.

  1. Wọn o ṣe imọra kuro nibi ẹgbin kekere ati nla ni majẹmu fun iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  2. Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n dunni mọ́ iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori iranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni ọpọlọpọ ni gbogbo igba lati fi kọṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ayaafi ni awọn ìṣesí ti wọn kọ ṣiṣe iranti nibẹ, gẹgẹ bíi asiko gbigbọ bukaata (itọ tabi igbẹ).

Ifiranṣẹ naa lọ pẹlu irọwọrọsẹ