explain-icon

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fi ori kanlẹ yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji ni iforikanlẹ; yoo si gbe ọwọ kọọkan jina si ibi ẹgbẹ ti o wa, gẹgẹ bii iyẹ meji, titi ti awọ abiya rẹ fi maa han; Ati pe eyi n bẹ ninu jijẹ ki apá méjèèjì da bii iyẹ ati gbigbe wọn jìnà gan si ẹgbẹ rẹ mejeeji.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣiṣe iṣesi yii ni ẹtọ nibi iforikanlẹ, oun naa ni gbigbe apa mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ mejeeji.
  • Olukirun lẹyin imaamu ti o ṣe wipe ara o maa ni ẹni ti o wa ni ẹgbẹ rẹ latara gbigbe ọwọ jina si ara wọn; ko tọ fun un ki o ṣe e.
  • O n bẹ nibi igbe ọwọ jina si ara wọn nibi iforikanlẹ awọn ọgbọn ati anfaani ti o pọ, ninu rẹ ni: Fifi ijafafa ati ini ìfẹ́ si irun han, ti o ba da ara le gbogbo oríkèé iforikanlẹ, gbogbo oríkèé kọọkan ni yio gba ẹtọ rẹ nibi ijọsin. Wọn tun sọ pe: Ọgbọn ti o wa nibi iyẹn ni pe o jọ itẹriba, o si de ogongo nibi fifi iwaju ati imu le ilẹ daadaa, ati pe bákannáà ki oríkèé kọọkan le da yatọ.