explain-icon

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba n ṣe anfaani fun obinrin ti ọkọ rẹ ku, ti ko ni ẹni kankan ti o maa moju to awọn alamọri rẹ, ati alaini ti o ni bukaata, ti o si n na owo fun wọn ni ẹni ti o n wa ẹsan lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ẹsan, o da gẹgẹ bii olujagun loju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n ki irun ni oru ti ko ki n rẹ ẹ, ati alaawẹ ti ko ki n túnu.

explain-icon

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  • Ṣisẹnilojukokoro lori iran-ara-ẹni-lọwọ ati ikun-ara-ẹni-lọwọ ati didi bukaata awọn ọlẹ.
  • Ijọsin ko gbogbo iṣẹ oloore sínú, ati pe ninu ijọsin ni riran awọn opo ati alaini lọwọ wa.
  • Ibnu Hubairọ sọ pe: Nnkan ti a gba lero ni pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa ko ẹsan alaawẹ ati eni ti o n dide loru ati olujagun fun un lẹẹkan naa; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe o duro sipo ọkọ fun opo...., o si duro ti alaini yẹn ti ko lee da duro fun ara rẹ, eleyii si na nǹkan ti o le si nǹkan ti o bukaata si, o si ṣe saara pẹlu igbiyanju rẹ, nitori naa anfaani rẹ wa ṣe deedee awẹ ati didide ati igbiyanju soju ọna Ọlọhun.